Luk 4:39-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. O si duro tirisi i, o ba ibà na wi; ibà si jọwọ rẹ̀ lọwọ: o si dide lọgan, o nṣe iranṣẹ fun wọn.

40. Nigbati õrùn si nwọ̀, gbogbo awọn ẹniti o ni olokunrun ti o li arunkarun, nwọn mu wọn tọ̀ ọ wá; o si fi ọwọ́ le olukuluku wọn, o si mu wọn larada.

41. Awọn ẹmi eṣu si jade lara ẹni pipọ pẹlu, nwọn nkigbe, nwọn si nwipe, Iwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọrun. O si mba wọn wi, kò si jẹ ki nwọn ki o fọhun: nitoriti nwọn mọ̀ pe Kristi ni iṣe.

42. Nigbati ilẹ si mọ́, o dide lọ si ibi ijù: ijọ enia si nwá a kiri, nwọn si tọ̀ ọ wá, nwọn si da a duro, nitori ki o má ba lọ kuro lọdọ wọn.

43. Ṣugbọn o si wi fun wọn pe, Emi kò le ṣaima wasu ijọba Ọlọrun fun ilu miran pẹlu: nitorina li a sá ṣe rán mi.

44. O si nwasu ninu sinagogu ti Galili.

Luk 4