25. Ṣugbọn mo wi fun nyin nitõtọ, opó pipọ li o wà ni Israeli nigba ọjọ woli Elijah, nigbati ọrun fi sé li ọdún mẹta on oṣù mẹfa, nigbati ìyan nla fi mu ká ilẹ gbogbo;
26. Kò si si ẹnikan ninu wọn ti a rán Elijah si, bikoṣe si obinrin opó kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni.
27. Ati adẹtẹ̀ pipọ ni mbẹ ni Israeli nigba woli Eliṣa; kò si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ́, bikoṣe Naamani ara Siria.
28. Nigbati gbogbo awọn ti o wà ninu sinagogu gbọ́ nkan wọnyi, inu ru wọn ṣùṣù,
29. Nwọn si dide, nwọn tì i sode si ẹhin ilu, nwọn si fà a lọ si bèbe òke nibiti nwọn gbé tẹ̀ ilu wọn do, ki nwọn ba le tari rẹ̀ li ogedengbe.
30. Ṣugbọn o kọja larin wọn, o ba tirẹ̀ lọ.
31. O si sọkalẹ wá si Kapernaumu, ilu kan ni Galili, o si nkọ́ wọn li ọjọ isimi.
32. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitori taṣẹ-taṣẹ li ọ̀rọ rẹ̀.
33. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu, ẹniti o li ẹmi aimọ́, o kigbe li ohùn rara,
34. O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun.