11. Ati pe li ọwọ́ wọn ni nwọn o gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta.
12. Jesu si dahùn o wi fun u pe, A ti sọ pe, Iwọ kò gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.
13. Nigbati Èṣu si pari idanwò na gbogbo, o fi i silẹ lọ di sã kan.
14. Jesu si fi agbara Ẹmí pada wá si Galili: okikí rẹ̀ si kàn kalẹ ni gbogbo àgbegbe ti o yiká.
15. O si nkọni ninu sinagogu wọn; a nyìn i logo lati ọdọ gbogbo awọn enia wá.
16. O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe.
17. A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si ṣí iwe na, o ri ibiti a gbé kọ ọ pe,
18. Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ.
19. Lati kede ọdún itẹwọgba Oluwa.
20. O si pa iwe na de, o tun fi i fun iranṣẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ.
21. O si bẹ̀rẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni Iwe-mimọ yi ṣẹ li etí nyin.
22. Gbogbo wọn si jẹri rẹ̀, ha si ṣe wọn si ọ̀rọ ore-ọfẹ ti njade li ẹnu rẹ̀. Nwọn si wipe, Ọmọ Josefu kọ́ yi?
23. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o pa owe yi si mi pe, Oniṣegun, wò ara rẹ sàn: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapernaumu, ṣe e nihinyi pẹlu ni ilẹ ara rẹ.
24. O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si woli ti a tẹwọgbà ni ilẹ baba rẹ̀.
25. Ṣugbọn mo wi fun nyin nitõtọ, opó pipọ li o wà ni Israeli nigba ọjọ woli Elijah, nigbati ọrun fi sé li ọdún mẹta on oṣù mẹfa, nigbati ìyan nla fi mu ká ilẹ gbogbo;
26. Kò si si ẹnikan ninu wọn ti a rán Elijah si, bikoṣe si obinrin opó kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni.
27. Ati adẹtẹ̀ pipọ ni mbẹ ni Israeli nigba woli Eliṣa; kò si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ́, bikoṣe Naamani ara Siria.
28. Nigbati gbogbo awọn ti o wà ninu sinagogu gbọ́ nkan wọnyi, inu ru wọn ṣùṣù,