Luk 11:16-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá.

17. Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó.

18. Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade.

19. Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin.

20. Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin.

21. Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia:

22. Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀.

23. Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká.

24. Nigbati ẹmi aimọ́ ba jade kuro lara enia, ama rìn kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati ko ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá.

25. Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ́.

26. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ.

27. O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu.

28. Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́.

29. Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ si iwipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli.

30. Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi.

31. Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.

Luk 11