11. Nigbana li awọn Ju si nwá a kiri nigba ajọ, wipe, Nibo li o wà?
12. Kikùn pipọ si wà larin awọn ijọ enia nitori rẹ̀: nitori awọn kan wipe, Enia rere ni iṣe: awọn miran wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn o ntàn enia jẹ ni.
13. Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju.
14. Nigbati ajọ de arin Jesu gòke lọ si tẹmpili o si nkọ́ni.
15. Ẹnu si yà awọn Ju, nwọn wipe, ọkunrin yi ti ṣe mọ̀ iwe, nigbati ko kọ́ ẹ̀kọ́?
16. Nitorina Jesu da wọn lohùn, o si wipe, Ẹkọ́ mi ki iṣe temi, bikoṣe ti ẹniti o rán mi.
17. Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.
18. Ẹniti nsọ̀ ti ara rẹ̀ nwá ogo ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti nwá ogo ẹniti o rán a, on li olõtọ, kò si si aiṣododo ninu rẹ̀.
19. Mose kò ha fi ofin fun yin, kò si ẹnikẹni ninu nyin ti o pa ofin na mọ́? Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá ọ̀na lati pa mi?
20. Ijọ enia dahùn nwọn si wipe, Iwọ li ẹmi èṣu: tani nwá ọ̀na lati pa ọ?
21. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, kìki iṣẹ àmi kan ni mo ṣe, ẹnu si yà gbogbo nyin.
22. Nitori eyi ni Mose fi ìkọlà fun nyin (kì iṣe nitoriti iṣe ti Mose, ṣugbọn ti awọn baba); nitorina ẹ si nkọ enia ni ilà li ọjọ isimi.
23. Bi enia ba ngbà ikọla li ọjọ isimi, ki a ma bà rú ofin Mose, ẹ ha ti ṣe mbinu si mi, nitori mo mu enia kan larada ṣáṣa li ọjọ isimi?
24. Ẹ máṣe idajọ nipa ode ara, ṣugbọn ẹ mã ṣe idajọ ododo.
25. Nigbana li awọn kan ninu awọn ara Jerusalemu wipe, Ẹniti nwọn nwá ọ̀na ati pa kọ́ yi?
26. Si wo o, o nsọrọ ni gbangba, nwọn kò si wi nkankan si i. Awọn olori ha mọ̀ nitõtọ pe, eyi ni Kristi na?
27. Ṣugbọn awa mọ̀ ibi ti ọkunrin yi gbé ti wá: ṣugbọn nigbati Kristi ba de, kò si ẹniti yio mọ̀ ibiti o gbé ti wà.