Joh 1:13-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Awọn ẹniti a bí, kì iṣe nipa ti ẹ̀jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹ̃ni kì iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun.

14. Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.

15. Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.

16. Nitori ninu ẹkún rẹ̀ ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ.

17. Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.

18. Ko si ẹniti o ri Ọlọrun rí; Ọmọ bíbi kanṣoṣo, ti mbẹ li õkan àiya Baba, on na li o fi i hàn.

19. Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?

20. O si jẹwọ, kò si sẹ́; o si jẹwọ pe, Emi kì iṣe Kristi na.

21. Nwọn si bi i pe, Tani iwọ ha iṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹ̃kọ. Iwọ ni woli na bi? O si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.

22. Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? ki awa ki o le fi èsi fun awọn ti o rán wa. Kili o wi ni ti ara rẹ?

23. O wipe, Emi li ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ ṣe ki ọ̀na Oluwa tọ́, gẹgẹ bi woli Isaiah ti wi.

24. Awọn ti a rán si jẹ ninu awọn Farisi.

25. Nwọn si bi i lẽre, nwọn si wi fun u pe, Njẹ ẽṣe ti iwọ fi mbaptisi, bi iwọ kì ibá ṣe Kristi na, tabi Elijah, tabi woli na?

26. Johanu da wọn lohùn, wipe, Emi nfi omi baptisi: ẹnikan duro larin nyin, ẹniti ẹnyin kò mọ̀;

27. On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀.

28. Nkan wọnyi li a ṣe ni Betani loke odò Jordani, nibiti Johanu gbé mbaptisi.

Joh 1