6. Ati awọn ọmọ Juda, ati awọn ọmọ Jerusalemu li ẹnyin ti tà fun awọn ara Griki, ki ẹnyin ba le sìn wọn jina kuro li agbègbe wọn.
7. Kiyesi i, emi o gbe wọn dide kuro nibiti ẹnyin ti tà wọn si, emi o si san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
8. Emi o si tà awọn ọmọkunrin nyin ati awọn ọmọbinrin nyin si ọwọ́ awọn ọmọ Juda, nwọn o si tà wọn fun awọn ara Sabia, fun orilẹ-ède kan ti o jinà rére, nitori Oluwa li o ti sọ ọ.
9. Ẹ kede eyi li ãrin awọn keferi; ẹ yà ogun si mimọ́, ẹ ji awọn alagbara, ẹ sunmọ tòsi, ẹ goke wá gbogbo ẹnyin ọkunrin ologun.
10. Ẹ fi irin ọkọ́ itulẹ̀ nyin rọ idà, ati dojé nyin rọ ọkọ̀: jẹ ki alailera wi pe, Ara mi le koko.
11. Ẹ kó ara nyin jọ, si wá, gbogbo ẹnyin keferi, ẹ si gbá ara nyin jọ yikakiri: nibẹ̀ ni ki o mu awọn alagbara rẹ sọkalẹ, Oluwa.
12. Ẹ ji, ẹ si goke wá si afonifojì Jehoṣafati ẹnyin keferi: nitori nibẹ̀ li emi o joko lati ṣe idajọ awọn keferi yikakiri.
13. Ẹ tẹ̀ doje bọ̀ ọ, nitori ikore pọ́n: ẹ wá, ẹ sọkalẹ; nitori ifunti kún, nitori awọn ọpọ́n kún rekọja, nitori ìwa-buburu wọn pọ̀.
14. Ọ̀pọlọpọ, ọ̀pọlọpọ li afonifojì idajọ, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ ni afonifojì idajọ.