1. JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
2. A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò.
3. Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò.
4. Obinrin na si mú awọn ọkunrin meji na, o si fi wọn pamọ́; o si wi bayi pe, Awọn ọkunrin kan wá sọdọ mi, ṣugbọn emi kò mọ̀ ibi ti nwọn ti wá.