19. Ati awo-koto wọnni, ati ohun ifọnna wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ìkoko wọnni, ati ọpa fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati ago wọnni, eyiti iṣe ti wura, wura, ati eyiti iṣe ti fadaka, fadaka, ni balogun iṣọ kó lọ.
20. Awọn ọwọ̀n meji, agbada nla kan, ati awọn malu idẹ mejila ti o wà labẹ ijoko, ti Solomoni ọba, ti ṣe fun ile Oluwa: idẹ gbogbo ohun-elo wọnyi alaini iwọ̀n ni.
21. Ati ọwọ̀n mejeji, giga ọwọ̀n kan ni igbọnwọ mejidilogun; okùn igbọnwọ mejila si yi i ka; ninipọn wọn si jẹ ika mẹrin, nwọn ni iho ninu.
22. Ati ọna-ori idẹ wà lori rẹ̀; giga ọna-ori kan si ni igbọnwọ marun, pẹlu iṣẹ wiwun ati pomegranate lara ọna ori wọnni yikakiri, gbogbo rẹ̀ jẹ ti idẹ: gẹgẹ bi wọnyi ni ọwọ̀n ekeji pẹlu, ati pomegranate rẹ̀.
23. Pomegranate mẹrindilọgọrun li o wà ni gbangba: gbogbo pomegranate lori iṣẹ wiwun na jẹ ọgọrun yikakiri.
24. Balogun iṣọ si mu Seraiah, olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah, alufa keji, ati awọn oluṣọ iloro mẹta:
25. Ati lati inu ilu o mu iwẹfa kan, ti o ni itọju awọn ologun; ati awọn ọkunrin meje ti nwọn nduro niwaju ọba, ti a ri ni ilu na; ati akọwe olori ogun ẹniti ntò awọn enia ilẹ na; ati ọgọta enia ninu awọn enia ilẹ na, ti a ri li ãrin ilu na.
26. Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu wọn, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.
27. Ọba Babeli si kọlu wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.
28. Eyi li awọn enia ti Nebukadnessari kó ni ìgbekun lọ: li ọdun keje, ẹgbẹdogun o le mẹtalelogun ara Juda.
29. Li ọdun kejidilogun Nebukadnessari, o kó ẹgbẹrin enia o le mejilelọgbọn ni igbèkun lati Jerusalemu lọ:
30. Li ọdun kẹtalelogun Nebukadnessari, Nebusaradani, balogun iṣọ, kó ọtadilẹgbẹrin enia o di marun awọn ara Juda ni igbekun lọ: gbogbo awọn enia na jẹ ẹgbẹtalelogun.