Jer 42:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ki Oluwa Ọlọrun rẹ le fi ọ̀na hàn wa ninu eyi ti awa iba rìn, ati ohun ti awa iba ṣe.

4. Jeremiah, woli, si wi fun wọn pe, emi gbọ́; wò o, emi o gbadura si Oluwa Ọlọrun nyin gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin; yio si ṣe, pe ohunkohun ti Oluwa yio fi da nyin lohùn emi o sọ ọ fun nyin; emi kì o ṣẹ nkankan kù fun nyin.

5. Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa.

6. Iba ṣe rere, iba ṣe ibi, awa o gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, sọdọ ẹniti awa rán ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.

7. O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá.

8. Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla.

9. O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀;

10. Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin.

Jer 42