11. Nigbana ni a o wi fun awọn enia yi ati fun Jerusalemu pe, Ẹfũfu gbigbona lati ibi giga ni iju niha ọmọbinrin enia mi, kì iṣe lati fẹ, tabi lati fẹnù.
12. Ẹfũfu ti o lagbara jù wọnyi lọ yio fẹ fun mi: nisisiyi emi pẹlu yio sọ̀rọ idajọ si wọn.
13. Sa wò o, on o dide bi awọsanma, kẹ̀kẹ rẹ̀ yio dabi ìji: ẹṣin rẹ̀ yara jù idì lọ. Egbe ni fun wa! nitori awa di ijẹ.
14. Jerusalemu! wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ là. Yio ti pẹ to ti iro asan yio wọ̀ si inu rẹ.
15. Nitori ohùn kan kede lati Dani wá, o si pokiki ipọnju lati oke Efraimu.
16. Ẹ wi fun awọn orilẹ-ède; sa wò o, kede si Jerusalemu, pe, awọn ọluṣọ-ogun ti ilẹ jijin wá, nwọn si sọ ohùn wọn jade si ilu Juda.
17. Bi awọn ti nṣọ oko, bẹ̃ni nwọn wà yi i kakiri: nitori o ti ṣọtẹ̀ si mi, li Oluwa wi.
18. Ìwa rẹ ati iṣe rẹ li o ti mu gbogbo ohun wọnyi bá ọ; eyi ni buburu rẹ, nitoriti o korò, nitoriti o de ọkàn rẹ.
19. Inu mi, inu mi! ẹ̀dun dùn mi jalẹ de ọkàn mi; ọkàn mi npariwo ninu mi; emi kò le dakẹ, Nitoriti iwọ, ọkàn mi, ngbọ́ iro fère, ati idagiri ogun.
20. Iparun lori iparun ni a nke; nitori gbogbo ilẹ li o ti parun, lojiji ni agọ mi di ijẹ, pẹlu aṣọ ikele mi ni iṣẹju kan.
21. Yio ti pẹ to ti emi o ri ọpagun, ti emi o si gbọ́ iro fère?