Jer 4:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Israeli bi iwọ o ba yipada, li Oluwa wi, yipada sọdọ mi; ati bi iwọ o ba mu irira rẹ kuro niwaju mi, iwọ kì o si rìn kiri:

2. Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.

3. Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ọkunrin Juda, ati Jerusalemu pe, tú ilẹ titun fun ara nyin, ki ẹ má si gbìn lãrin ẹ̀gun.

4. Ẹ kọ ara nyin ni ilà fun Oluwa, ki ẹ si mu awọ ikọla ọkàn nyin kuro, ẹnyin enia Juda ati olugbe Jerusalemu, ki ikannu mi ki o má ba jade bi iná, ki o si jo tobẹ̃ ti kò si ẹniti o le pa a, nitori buburu iṣe nyin.

5. Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì.

6. Ẹ gbé ọpagun soke siha Sioni; ẹ kuro, ẹ má duro: nitori emi o mu buburu lati ariwa wá pẹlu ibajẹ nlanla.

7. Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe.

8. Nitori eyi, di amure aṣọ ọ̀fọ, pohùnrere ki o si sọkun: nitori ibinu gbigbona Oluwa kò lọ kuro lọdọ wa.

9. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ọkàn ọba yio nù, ati ọkàn awọn ijoye: awọn alufa yio si dãmu, hà yio si ṣe awọn woli.

Jer 4