Jer 4:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Israeli bi iwọ o ba yipada, li Oluwa wi, yipada sọdọ mi; ati bi iwọ o ba mu irira rẹ kuro niwaju mi, iwọ kì o si rìn kiri:

2. Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.

3. Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ọkunrin Juda, ati Jerusalemu pe, tú ilẹ titun fun ara nyin, ki ẹ má si gbìn lãrin ẹ̀gun.

4. Ẹ kọ ara nyin ni ilà fun Oluwa, ki ẹ si mu awọ ikọla ọkàn nyin kuro, ẹnyin enia Juda ati olugbe Jerusalemu, ki ikannu mi ki o má ba jade bi iná, ki o si jo tobẹ̃ ti kò si ẹniti o le pa a, nitori buburu iṣe nyin.

5. Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì.

6. Ẹ gbé ọpagun soke siha Sioni; ẹ kuro, ẹ má duro: nitori emi o mu buburu lati ariwa wá pẹlu ibajẹ nlanla.

7. Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe.

8. Nitori eyi, di amure aṣọ ọ̀fọ, pohùnrere ki o si sọkun: nitori ibinu gbigbona Oluwa kò lọ kuro lọdọ wa.

9. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ọkàn ọba yio nù, ati ọkàn awọn ijoye: awọn alufa yio si dãmu, hà yio si ṣe awọn woli.

10. Nigbana ni mo wipe, Ye! Oluwa Ọlọrun! nitõtọ iwọ ti tan awọn enia yi ati Jerusalemu jẹ gidigidi, wipe, Ẹnyin o ni alafia; nigbati idà wọ inu ọkàn lọ.

Jer 4