25. Ṣugbọn Elnatani ati Delaiah ati Gemariah bẹbẹ lọdọ ọba ki o máṣe fi iwe-kiká na joná, kò si fẹ igbọ́ ti wọn.
26. Ṣugbọn ọba paṣẹ fun Jerameeli, ọmọ Hameleki, ati Seraiah, ọmọ Asraeli, ati Ṣelemiah, ọmọ Abdeeli, lati mu Baruku akọwe, ati Jeremiah woli: ṣugbọn Oluwa fi wọn pamọ.
27. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá, lẹhin ti ọba ti fi iwe-kiká na ati ọ̀rọ ti Baruku kọ lati ẹnu Jeremiah wá joná, wipe,
28. Tun mu iwe kiká miran, ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ iṣaju sinu rẹ̀ ti o wà ninu iwe-kiká ekini, ti Jehoiakimu, ọba Juda, ti fi joná.
29. Iwọ o si sọ niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti fi iwe-kiká yi joná o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi kọwe sinu rẹ̀, pe: Lõtọ ọba Babeli yio wá yio si pa ilẹ yi run, yio si pa enia ati ẹran run kuro ninu rẹ̀?