Jer 33:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi.

14. Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu ohun rere na, ti emi ti leri fun ilẹ Israeli ati fun ile Juda, ṣẹ.

15. Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, emi o jẹ ki Ẹka ododo ki o hu soke fun Dafidi; ẹniti yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.

16. Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.

17. Nitori bayi li Oluwa wi; A kì o fẹ ọkunrin kan kù lọdọ Dafidi lati joko lori itẹ́ ile Israeli lailai.

18. Bẹ̃ni awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, kì yio fẹ ọkunrin kan kù niwaju mi lati ru ẹbọ sisun, ati lati dana ọrẹ ohun jijẹ, ati lati ṣe irubọ lojojumọ.

19. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, wipe,

20. Bayi li Oluwa wi; Bi ẹnyin ba le bà majẹmu mi ti ọsan jẹ, ati majẹmu mi ti oru, tí ọsan ati oru kò le si li akoko wọn;

21. Nigbana ni majẹmu mi pẹlu Dafidi, iranṣẹ mi le bajẹ, pe ki on ki o má le ni ọmọ lati joko lori itẹ rẹ̀; ati pẹlu awọn ọmọ Lefi, awọn alufa, awọn iranṣẹ mi.

22. Gẹgẹ bi a kò ti le ka iye ogun-ọrun, tabi ki a le wọ̀n iyanrin eti okun: bẹ̃ni emi o sọ iru-ọmọ Dafidi iranṣẹ mi di pupọ, ati awọn ọmọ Lefi, ti nṣe iranṣẹ fun mi.

23. Ọ̀rọ Oluwa si tọ Jeremiah wá, wipe,

Jer 33