5. Nitori bayi li Oluwa wi; Awa ti gbọ́ ohùn ìwa-riri, ẹ̀ru, kì si iṣe ti alafia.
6. Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkunrin a mã rọbi ọmọ: Ẽṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkunrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn, bi obinrin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro?
7. Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹ̃ ti kò si ọkan bi iru rẹ̀: o jẹ àkoko wahala fun Jakobu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ̀.
8. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi o si ṣẹ àjaga kuro li ọrùn rẹ, emi o si ja ìde rẹ, awọn alejo kì yio si mu ọ sìn wọn mọ:
9. Ṣugbọn nwọn o ma sin Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn, ẹniti emi o gbe kalẹ fun wọn.
10. Njẹ nisisiyi, má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi; ki o má si fòya, iwọ Israeli: nitorina sa wò o, emi o gbà ọ lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati igbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì yio si dẹruba a.
11. Nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ: bi emi tilẹ ṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi kì yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn, emi kì o jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.
12. Nitori bayi li Oluwa wi, Ifarapa rẹ jẹ aiwotan, ọgbẹ rẹ si jẹ aijina.
13. Kò si ẹniti o gba ọ̀ran rẹ rò, lati dì i, ọja imularada kò si.
14. Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,
15. Ẽṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikãnu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ; ẹ̀ṣẹ rẹ si pọ̀ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ.