Ẽṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikãnu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ; ẹ̀ṣẹ rẹ si pọ̀ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ.