2. Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, pe, Iwọ kọ gbogbo ọ̀rọ ti mo ti ba ọ sọ sinu iwe kan.
3. Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu igbekun awọn enia mi, Israeli ati Juda, pada, li Oluwa wi: emi o si mu ki nwọn pada bọ̀ si ilẹ ti emi fi fun awọn baba wọn, nwọn o si ni i.
4. Wọnyi si li ọ̀rọ ti Oluwa sọ niti Israeli ati niti Juda.
5. Nitori bayi li Oluwa wi; Awa ti gbọ́ ohùn ìwa-riri, ẹ̀ru, kì si iṣe ti alafia.
6. Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkunrin a mã rọbi ọmọ: Ẽṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkunrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn, bi obinrin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro?
7. Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹ̃ ti kò si ọkan bi iru rẹ̀: o jẹ àkoko wahala fun Jakobu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ̀.
8. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi o si ṣẹ àjaga kuro li ọrùn rẹ, emi o si ja ìde rẹ, awọn alejo kì yio si mu ọ sìn wọn mọ:
9. Ṣugbọn nwọn o ma sin Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn, ẹniti emi o gbe kalẹ fun wọn.
10. Njẹ nisisiyi, má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi; ki o má si fòya, iwọ Israeli: nitorina sa wò o, emi o gbà ọ lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati igbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì yio si dẹruba a.