Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu igbekun awọn enia mi, Israeli ati Juda, pada, li Oluwa wi: emi o si mu ki nwọn pada bọ̀ si ilẹ ti emi fi fun awọn baba wọn, nwọn o si ni i.