Jer 30:14-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,

15. Ẽṣe ti iwọ nkigbe nitori ifarapa rẹ? ikãnu rẹ jẹ aiwotan, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ; ẹ̀ṣẹ rẹ si pọ̀ si i, nitorina ni emi ti ṣe ohun wọnyi si ọ.

16. Nitorina gbogbo awọn ti o jẹ ọ, li a o jẹ; ati gbogbo awọn ọta rẹ, olukuluku wọn, ni yio lọ si igbekun: ati awọn ti o kó ọ yio di kikó, ati gbogbo awọn ti o fi ọ ṣe ijẹ li emi o fi fun ijẹ.

17. Nitori emi o fi ọja imularada lè ọ, emi o si wò ọgbẹ rẹ san, li Oluwa wi; nitori nwọn pè ọ li ẹniti a le jade; Sioni, ti ẹnikan kò ṣafẹri rẹ̀!

18. Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o tun mu igbekun agọ Jakobu pada bọ̀; emi o si ṣãnu fun ibugbe rẹ̀; a o si kọ́ ilu na sori okiti rẹ̀, a o si ma gbe ãfin gẹgẹ bi ilana rẹ̀.

19. Ati lati inu wọn ni ọpẹ́ ati ohùn awọn ti nyọ̀ yio ti jade: emi o si mu wọn bi si i, nwọn kì o si jẹ diẹ; emi o ṣe wọn li ogo pẹlu, nwọn kì o si kere.

20. Awọn ọmọ wọn pẹlu yio ri bi ti iṣaju, ijọ wọn li a o fi idi rẹ̀ mulẹ niwaju mi, emi o si jẹ gbogbo awọn ti o ni wọn lara niya.

21. Ọlọla rẹ̀ yio si jẹ lati inu ara wọn wá, alakoso rẹ̀ lati ãrin rẹ̀; emi o si mu u sunmọ tosi, on o si sunmọ ọdọ mi: nitori tani ẹniti o mura ọkàn rẹ̀ lati sunmọ ọdọ mi? li Oluwa wi.

22. Ẹnyin o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin.

23. Wò o, afẹfẹ iji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori oluṣe-buburu.

24. Ibinu kikan Oluwa kì o pada, titi on o fi ṣe e, ati titi on o fi mu èro ọkàn rẹ̀ ṣẹ: li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.

Jer 30