Jer 30:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa wá, wipe.

2. Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi, pe, Iwọ kọ gbogbo ọ̀rọ ti mo ti ba ọ sọ sinu iwe kan.

3. Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu igbekun awọn enia mi, Israeli ati Juda, pada, li Oluwa wi: emi o si mu ki nwọn pada bọ̀ si ilẹ ti emi fi fun awọn baba wọn, nwọn o si ni i.

4. Wọnyi si li ọ̀rọ ti Oluwa sọ niti Israeli ati niti Juda.

5. Nitori bayi li Oluwa wi; Awa ti gbọ́ ohùn ìwa-riri, ẹ̀ru, kì si iṣe ti alafia.

6. Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkunrin a mã rọbi ọmọ: Ẽṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkunrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn, bi obinrin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro?

7. Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹ̃ ti kò si ọkan bi iru rẹ̀: o jẹ àkoko wahala fun Jakobu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ̀.

Jer 30