Jer 27:20-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Eyi ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kò mu lọ nigbati o mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli, pẹlu gbogbo awọn ọlọla Juda ati Jerusalemu;

21. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, niti ohun-èlo ti o kù ni ile Oluwa, ati ni ile ọba Juda ati Jerusalemu.

22. A o kó wọn lọ si Babeli, nibẹ ni nwọn o wà titi di ọjọ na ti emi o bẹ̀ wọn wò, li Oluwa wi, emi o si mu wọn goke wá, emi o si mu wọn pada wá si ibi yi.

Jer 27