Jer 27:17-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ẹ máṣe gbọ́ ti wọn; ẹ sin ọba Babeli, ẹ si yè: ẽṣe ti ilu yi yio fi di ahoro?

18. Ṣugbọn bi nwọn ba ṣe woli, ati bi ọ̀rọ Oluwa ba wà pẹlu wọn, jẹ ki nwọn ki o bẹbẹ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ki ohun-èlo iyokù ni ile Oluwa ati ni ile ọba Judah, ati ni Jerusalemu, ki nwọn ki o máṣe lọ si Babeli.

19. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti opó mejeji, ati niti agbada nla, ati niti ipilẹṣẹ, ati niti ohun-èlo iyokù ti o kù ni ilu yi.

Jer 27