18. Nitorina bayi li Oluwa wi nitori Jehoiakimu ọmọ Josiah, ọba Juda, nwọn kì yio ṣọ̀fọ fun u, wipe, Oṣe! arakunrin mi! tabi Oṣe! arabinrin mi! nwọn kì o ṣọ̀fọ fun u pe, Oṣe, oluwa! tabi Oṣe, ọlọla!
19. A o sin i ni isinkú kẹtẹkẹtẹ, ti a wọ́ ti a si sọ junù kuro ni ẹnu-bode Jerusalemu.
20. Goke lọ si Lebanoni, ki o si ke, ki o si gbe ohùn rẹ soke ni Baṣani, ki o kigbe lati Abarimu, nitori a ti ṣẹ́ gbogbo olufẹ rẹ tutu,
21. Emi ti ba ọ sọ̀rọ ni ìgba ire rẹ; iwọ wipe, emi kì yio gbọ́. Eyi ni ìwa rẹ lati igba ewe rẹ wá, ti iwọ kò si gba ohùn mi gbọ.
22. Ẹfũfu yio fẹ gbogbo oluṣọ-agutan rẹ lọ, ati awọn olufẹ rẹ yio lọ si ìgbekun: nitõtọ, ni wakati na ni oju yio tì ọ, iwọ o si dãmu nitori gbogbo buburu rẹ.
23. Iwọ, olugbe Lebanoni, ti o tẹ́ itẹ si ori igi kedari, iwọ o ti jẹ otoṣi to, nigbati irora ba deba ọ, irora bi obinrin ti nrọbi!
24. Bi emi ti wà, li Oluwa wi, bi Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, tilẹ jẹ oruka-èdidi lọwọ ọtun mi, sibẹ̀ emi o fà ọ tu kuro nibẹ.
25. Emi o si fi ọ le ọwọ awọn ti o nwá ẹmi rẹ, ati le ọwọ ẹniti iwọ bẹ̀ru rẹ̀, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati ọwọ awọn ara Kaldea.
26. Emi o tì ọ sode, ati iya rẹ ti o bi ọ si ilẹ miran, nibiti a kò bi nyin si; nibẹ li ẹnyin o si kú.
27. Ṣugbọn ilẹ na ti ẹnyin fẹ li ọkàn nyin lati pada si, nibẹ ni ẹnyin kì o pada si mọ.
28. Ọkunrin yi, Koniah, ohun-èlo ẹlẹgan, fifọ ha ni bi? o ha dabi ohun-èlo ti kò ni ẹwà lara? ẽṣe ti a tì wọn jade, on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ti a si le wọn jade si ilẹ ti nwọn kò mọ̀?
29. Ilẹ! ilẹ! ilẹ! gbọ́ ọ̀rọ Oluwa!
30. Bayi li Oluwa wi, Ẹ kọwe pe, ọkunrin yi alailọmọ ni, ẹniti kì yio ri rere li ọjọ aiye rẹ̀: nitori ọkan ninu iru-ọmọ rẹ̀ kì yio ri rere, ti yio fi joko lori itẹ Dafidi, ti yio si fi tun jọba lori Juda.