5. Bi iwọ ba ba ẹlẹsẹ rìn, ti ãrẹ si mu ọ, iwọ o ha ti ṣe ba ẹlẹṣin dije? ati pẹlu ni ilẹ alafia, bi iwọ ba ni igbẹkẹle, kini iwọ o ṣe ninu ẹkún odò Jordani?
6. Nitori pẹlupẹlu, awọn arakunrin rẹ, ati ile baba rẹ, awọn na ti hùwa ẹ̀tan si ọ, lõtọ, awọn na ti ho le ọ: Má gbẹkẹle wọn, bi nwọn tilẹ ba ọ sọ̀rọ daradara.
7. Emi ti kọ̀ ile mi silẹ, mo ti fi ogún mi silẹ; mo ti fi olufẹ ọ̀wọn ọkàn mi le ọta rẹ̀ lọwọ.
8. Ogún mi di kiniun ninu igbo fun mi; on kigbe soke si mi; nitorina ni mo ṣe korira rẹ̀.
9. Ogún mi di ẹranko ọ̀wawa fun mi, ẹranko yi i kakiri, ẹ lọ, ẹ ko gbogbo ẹran igbẹ jọ pọ̀, ẹ mu wọn wá jẹ.
10. Ọ̀pọlọpọ oluṣọ-agutan ba ọgba ajara mi jẹ, nwọn tẹ ipin oko mi mọlẹ labẹ ẹsẹ wọn, nwọn ti sọ ipin oko mi ti mo fẹ di aginju ahoro.
11. Nwọn ti sọ ọ di ahoro, o ṣọ̀fọ fun mi bi ahoro: gbogbo ilẹ ti di ahoro, nitori ti kò si ẹnikan ti o rò li ọkàn rẹ̀.
12. Awọn abanijẹ ti gori gbogbo ibi giga wọnni ni ọ̀dan, nitori idà Oluwa yio pa lati ikangun de ikangun ekeji ilẹ na, alafia kò si fun gbogbo alãye.