6. Nigbana ni ọkan ninu awọn serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹṣẹ́-iná li ọwọ́ rẹ̀, ti o ti fi ẹmú mu lati ori pẹpẹ wá.
7. O si fi kàn mi li ẹnu, o si wipe, Kiyesi i, eyi ti kàn etè rẹ, a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọ ẹ̀ṣẹ rẹ nù.
8. Emi si gbọ́ ohùn Oluwa pẹlu wipe, Tali emi o rán, ati tani yio si lọ fun wa? Nigbana li emi wipe, Emi nĩ; rán mi.
9. On si wipe, Lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, Ni gbigbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri, ẹ ri, ṣugbọn ẹnyin ki yio si mọ̀ oye.
10. Mu ki aiya awọn enia yi ki o sebọ́, mú ki eti wọn ki o wuwo, ki o si di wọn li oju, ki nwọn ki o má ba fi eti wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba mu wọn li ara dá.
11. Nigbana ni emi wipe, Oluwa, yio ti pẹ to? O si dahùn pe, Titi awọn ilu-nla yio fi di ahoro, li aisi olugbe, ati awọn ile li aisi enia, ati ilẹ yio di ahoro patapata.