4. Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi.
5. Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla.
6. Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ.
7. Yio si ṣe, afonifoji àṣayan rẹ yio kún fun kẹkẹ́, awọn ẹlẹṣin yio si tẹ́ ogun niha ẹnu odi.