Isa 22:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti afonifoji ojuran. Kili o ṣe ọ nisisiyi, ti iwọ fi gùn ori ile lọ patapata?

2. Iwọ ti o kún fun ìrukerudo, ilu aitòro, ilu ayọ̀: a kò fi idà pa awọn okú rẹ, bẹ̃ni nwọn kò kú li ogun.

3. Gbogbo awọn alakoso rẹ ti jumọ sa lọ, awọn tafàtafà ti dì wọn ni igbekun: gbogbo awọn ti a ri ninu rẹ li a dì jọ, ti o ti sa lati okere wá.

4. Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi.

5. Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla.

Isa 22