13. Awọn ọmọ-alade Soani di aṣiwère, a tàn awọn ọmọ-alade Nofi jẹ; ani awọn ti iṣe pataki ẹyà rẹ̀.
14. Oluwa ti mí ẽmi iyapa si inu rẹ̀ na: nwọn si ti mu Egipti ṣina ninu gbogbo iṣẹ inu rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀muti enia ti nta gbọngbọ́n ninu ẽbi rẹ̀.
15. Bẹ̃ni kì yio si iṣẹkiṣẹ́ fun Egipti, ti ori tabi ìru, ẹka tabi oko-odò, le ṣe.
16. Li ọjọ na ni Egipti yio dabi obinrin; yio si warìri, ẹ̀ru yio si bà a nitori mimì ọwọ́ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o mì le e lori.
17. Ilẹ Juda yio si di ẹ̀ru fun Egipti, olukuluku ẹniti o dá a sọ ninu rẹ̀ yio tikararẹ̀ bẹ̀ru, nitori ìmọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o ti gbà si i.
18. Li ọjọ na ni ilu marun ni ilẹ Egipti yio fọ̀ ède Kenaani, ti nwọn o sì bura si Oluwa awọn ọmọ-ogun; a o ma pè ọkan ni Ilu ìparun.