1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti Egipti. Kiyesi i, Oluwa ngùn awọsanma ti o yara, yio si wá si Egipti: a o si ṣi ipò awọn òriṣa Egipti pàda niwaju rẹ̀, aiya Egipti yio yọ́ li ãrin rẹ̀.
2. Emi o si gbe Egipti dide si Egipti: olukuluku yio si ba arakunrin rẹ̀ jà, ati olukuluku aladugbò rẹ̀; ilu yio dojukọ ilu, ati ijọba yio dojukọ ijọba.
3. Ẹmi Egipti yio si rẹ̀wẹsi lãrin inu rẹ̀; emi o si pa ìmọ inu rẹ̀ run: nwọn o si wá a tọ̀ òriṣa lọ, ati sọdọ awọn atuju, ati sọdọ awọn ajẹ́, ati sọdọ awọn oṣó;
4. Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Awọn ara Egipti li emi o fi le oluwa onrorò li ọwọ́; ọba ti o muna yio ṣe akoso wọn.
5. Omi yio si buṣe li okun, a o si fi odò ṣofo, yio si gbẹ.
6. Odò yio si di rirùn; odò ãbo li a o sọ di ofo, ti a o si gbọ́n gbẹ; oko-odò ati iyè yio rọ.
7. Oko-tutù ni ipadò, li ẹnu odò, ati ohun gbogbo ti a gbìn sipadò, ni yio rọ, yio funka, kì yio si si mọ.
8. Awọn apẹja yio gbàwẹ pẹlu, ati gbogbo awọn ti nfì ìwọ li odò yio pohùnrére-ẹkun; ati awọn ti nda àwọn li odò yio sorikọ́.
9. Pẹlupẹlu awọn ti nṣiṣẹ ọ̀gbọ daradara, ati awọn ti nwun asọ-àla yio dãmu.
10. A o si fọ́ wọn ni ipilẹ rẹ̀, gbogbo awọn alagbàṣe li a o bà ni inu jẹ.
11. Nitõtọ òpe ni awọn ọmọ-alade Soani, ìmọ awọn ìgbimọ ọlọgbọn Farao di wère: ẹ ha ti ṣe sọ fun Farao, pe, Emi li ọmọ ọlọgbọn, ọmọ awọn ọba igbãni?
12. Awọn dà? awọn ọlọgbọn rẹ dà? si jẹ ki wọn sọ fun ọ nisisiyi, si jẹ ki wọn mọ̀ ete ti Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pa le Egipti.
13. Awọn ọmọ-alade Soani di aṣiwère, a tàn awọn ọmọ-alade Nofi jẹ; ani awọn ti iṣe pataki ẹyà rẹ̀.
14. Oluwa ti mí ẽmi iyapa si inu rẹ̀ na: nwọn si ti mu Egipti ṣina ninu gbogbo iṣẹ inu rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀muti enia ti nta gbọngbọ́n ninu ẽbi rẹ̀.
15. Bẹ̃ni kì yio si iṣẹkiṣẹ́ fun Egipti, ti ori tabi ìru, ẹka tabi oko-odò, le ṣe.
16. Li ọjọ na ni Egipti yio dabi obinrin; yio si warìri, ẹ̀ru yio si bà a nitori mimì ọwọ́ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o mì le e lori.