1. ỌRỌ-imọ̀ niti Moabu. Nitori li oru li a sọ Ari ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ; nitori li oru li a sọ Kiri ti Moabu di ahoro, a si mu u dakẹ;
2. On ti goke lọ si Bajiti, ati si Diboni, ibi giga wọnni, lati sọkun: Moabu yio hu lori Nebo, ati lori Medeba: gbogbo ori wọn ni yio pá, irungbọ̀n olukulùku li a o fá.
3. Ni igboro ni wọn o da aṣọ-ọ̀fọ bò ara wọn: lori okè ilé wọn, ati ni igboro wọn, olukuluku yio hu, yio si ma sọkun pẹ̀rẹpẹ̀rẹ.
4. Heṣboni yio si kigbe, ati Eleale: a o si gbọ́ ohùn wọn titi dé Jahasi: nitorina ni awọn ọmọ-ogun Moabu ti o hamọra yio kigbe soke; ọkàn rẹ̀ yio bajẹ fun ara rẹ̀.
5. Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke.
6. Nitori awọn omi Nimrimu yio di ahoro: nitori koriko nrọgbẹ, eweko nkú lọ, ohun tutù kan kò si.