Isa 12 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ọpẹ́

1. ATI li ọjọ na iwọ o si wipe, Oluwa, emi o yìn ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu.

2. Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹ̀ru: nitori Oluwa Jehofah li agbara mi ati orin mi; on pẹlu si di igbala mi.

3. Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá.

4. Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke.

5. Kọrin si Oluwa: nitori o ti ṣe ohun didara: eyi di mimọ̀ ni gbogbo aiye.

6. Kigbe, si hó, iwọ olugbe Sioni: nitori ẹni titobi ni Ẹni-Mimọ́ Israeli li ãrin rẹ.