Isa 11:12-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn aṣati Israeli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá.

13. Ilara Efraimu yio si tan kuro; Efraimu ki yio ṣe ilara Juda, Juda ki yio si bà Efraimu ninu jẹ.

14. Ṣugbọn nwọn o si fò mọ ejika awọn Filistini siha iwọ̀-õrun; nwọn o jùmọ bà awọn ti ilà-õrun jẹ: nwọn o si gbe ọwọ́ le Edomu ati Moabu; awọn ọmọ Ammoni yio si gbà wọn gbọ́.

15. Oluwa yio si pa ahọn okun Egipti run tũtũ; ẹfũfu lile rẹ̀ ni yio si mì ọwọ́ rẹ̀ lori odo na, yio si lù u ni iṣàn meje, yio si jẹ ki enia rekọja ni batà gbigbẹ.

16. Ọna opopo kan yio si wà fun iyokù awọn enia rẹ̀, ti yio kù, lati Assiria; gẹgẹ bi o ti ri fun Israeli li ọjọ ti o goke jade kuro ni ilẹ Egipti.

Isa 11