2. Sam 1:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o rò fun u wipe, Nibo ni iwọ ti wá? On si da a li ohùn pe, Ọmọ alejo kan, ara Amaleki li emi iṣe.

14. Dafidi si wi fun u pe, E ti ri ti iwọ kò fi bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo Oluwa?

15. Dafidi si pe ọkan ninu awọn ọmọdekunrin, o si wipe, Sunmọ ọ, ki o si kọ lu u. O si kọ lu u, on si kú.

16. Dafidi si wi fun u pe Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo Oluwa.

17. Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀:

18. O si pa aṣẹ lati kọ́ awọn ọmọ Juda ni ilò ọrun: wõ, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri.

19. Ẹwà rẹ Israeli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu!

20. Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si ṣe kokiki rẹ̀ ni igboro Aṣkeloni; ki awọn ọmọbinrin Filistini ki o má ba yọ̀, ki ọmọbinrin awọn alaikọla ki o má ba yọ̀.

2. Sam 1