9. Bẹ̃ni Manasse mu ki Judah ati awọn ti ngbe Jerusalemu ki o yapa, ati lati ṣe buburu jù awọn orilẹ-ède lọ, awọn ẹniti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli.
10. Oluwa si ba Manasse wi ati awọn enia rẹ̀; ṣugbọn nwọn kò kiyesi i.
11. Nitorina li Oluwa mu awọn balogun ogun Assiria wá ba wọn, ti nwọn fi ìwọ mu Manasse, nwọn si de e li ẹ̀wọn, nwọn mu u lọ si Babeli.
12. Nigbati o si wà ninu wahala, o bẹ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ gidigidi niwaju Ọlọrun awọn baba rẹ̀,
13. O si gbadura si i: Ọlọrun si gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, o si tun mu u pada wá si Jerusalemu sinu ijọba rẹ̀. Nigbana ni Manasse mọ̀ pe: Oluwa, On li Ọlọrun.
14. Njẹ lẹhin eyi, o mọ odi kan lẹhin ilu Dafidi, niha ìwọ-õrun Gihoni, li àfonifoji, ani li atiwọ ẹnu-bode ẹja, o si yi Ofeli ka, o si mọ ọ ga soke gidigidi, o si fi balogun sinu gbogbo ilú olodi Juda wọnni.
15. O si kó awọn àjeji ọlọrun ati ere kuro ni ile Oluwa, ati gbogbo pẹpẹ ti o ti tẹ́ lori òke ile Oluwa ati ni Jerusalemu, o si kó wọn danu kuro ni ilu.
16. O si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, o si rú ẹbọ alafia ati ẹbọ ọpẹ lori rẹ̀, o si paṣẹ fun Juda lati ma sìn Oluwa Ọlọrun Israeli.
17. Sibẹ awọn enia nṣe irubọ ni ibi giga wọnni, kiki si Oluwa, Ọlọrun wọn nikan ni.