Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sin i ninu iboji awọn ọmọ Dafidi: ati gbogbo Juda ati awọn ti ngbe Jerusalemu ṣe ẹyẹ fun u ni iku rẹ̀. Manasse ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.