2. Kro 33:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI ọdun mejila ni Manasse, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu:

2. Ṣugbọn o ṣe buburu li oju Oluwa, bi irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.

3. Nitori ti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀, ti wó lulẹ, o si gbé pẹpẹ wọnni soke fun Baalimu, o si ṣe ere oriṣa, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.

4. O tẹ́ pẹpẹ pẹlu ni ile Oluwa, niti eyiti Oluwa ti sọ pe; Ni Jerusalemu li orukọ mi yio wà lailai.

5. O si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li àgbala mejeji ile Oluwa.

6. O si mu ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná àfonifoji ọmọ Hinnomu: ati pẹlu o nṣe akiyesi afọṣẹ, o si nlò alupayida, o si nṣe ajẹ́, o si mba okú lò, ati pẹlu oṣó: o ṣe buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.

2. Kro 33