2. Kro 29:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Nigbana ni nwọn wọle tọ̀ Hesekiah ọba, nwọn si wipe: Awa ti gbá ile Oluwa mọ́, ati pẹpẹ ẹbọ sisun, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀, ati tabili akara-ifihan, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀.

19. Pẹlupẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ́ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, li akokò ijọba rẹ̀, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ́, si kiyesi i, nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ Oluwa.

20. Nigbana ni Hesekiah, ọba, dide ni kutukutu; o si kó awọn olori ilu jọ, o si gòke lọ sinu ile Oluwa.

21. Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa.

2. Kro 29