6. Ṣugbọn tani to lati kọ́ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọ́le fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rẹ̀?
7. Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ.
8. Fi ìti-igi kedari, ati firi, ati algumu ranṣẹ si mi pẹlu, lati Lebanoni wá: emi sa mọ̀ pe awọn iranṣẹ rẹ le gbọ́ngbọn ati ké igi ni Lebanoni; si kiyesi i, awọn ọmọ-ọdọ mi yio wà pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ:
9. Ani lati pèse ìti-igi lọpọlọpọ silẹ fun mi: nitori ile na ti emi mura lati kọ́ tobi, o si ya ni lẹnu.
10. Si wò o, emi o fi fun ilo awọn akégi, ti nké ìti-igi, lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ẹgbãwa òṣuwọn alikama fun onjẹ, ati ẹgbãwa òṣuwọn barli ati ẹgbãwa bati ọti-waini, ati ẹgbãwa bati ororo.
11. Nigbana ni Huramu, ọba Tire, kọwe dahùn o si ranṣẹ si Solomoni pe, Nitori ti Oluwa fẹran awọn enia rẹ̀ li o ṣe fi ọ jọba lori wọn.
12. Huramu si wipe, Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o da ọrun on aiye, ẹniti o fun Dafidi ọba ni ọlọgbọ́n ọmọ, ti o mọ̀ ọgbọ́n ati oye, ti o le kọ́ ile fun Oluwa, ati ile fun ijọba rẹ̀.
13. Njẹ nisisiyi emi rán ọkunrin ọlọgbọ́n kan, ti o mọ̀ oye, ani Huramu-Abi,
14. Ọmọ obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin Dani: baba rẹ̀ si ṣe ọkunrin ara Tire ti o gbọ́ngbọn ati ṣiṣẹ ni wura, ati ni fadakà, ni idẹ, ni irin, ni okuta, ati ni ìti-igi, ni èse-aluko, ni alaró, ati ni ọ̀gbọ daradara, ati òdodó, lati gbẹ́ oniruru ohun gbigbẹ́ pẹlu, ati lati ṣe awari ìmọ ẹrọ gbogbo ti a o fi fun u ṣe, pẹlu awọn ọlọgbọ́n rẹ, ati pẹlu awọn ọlọgbọ́n oluwa mi Dafidi, baba rẹ.
15. Njẹ nitorina alikama ati ọkà barli, ororo, ati ọti-waini na ti oluwa mi ti sọ, jẹ ki o fi ranṣẹ si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.