Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ.