2. Kro 11:10-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ati Sora, ati Aijaloni, ati Hebroni, ti o wà ni Juda ati ni Benjamini, awọn ilu olodi.

11. O si mu awọn ilu olodi lagbara, o si fi awọn balogun sinu wọn ati akojọ onjẹ, ati ororo ati ọti-waini.

12. Ati ni olukuluku ilu li o fi asà ati ọ̀kọ si, o si mu wọn lagbara gidigidi, o si ni Juda ati Benjamini labẹ rẹ̀.

13. Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ti o wà ni gbogbo Israeli, tọ̀ ọ lọ lati gbogbo ibugbe wọn wá.

14. Nitori ti awọn ọmọ Lefi fi ìgberiko wọn silẹ, ati ini wọn, nwọn si lọ si Juda ati Jerusalemu: nitori Jeroboamu ati awọn ọmọ rẹ̀ ti le wọn kuro lati ma ṣiṣẹ alufa fun Oluwa.

15. O si yàn awọn alufa fun ibi-giga wọnni, ati fun awọn ere-obukọ ati fun ẹ̀gbọrọ-malu ti o ti ṣe.

16. Lẹhin wọn iru awọn ti o fi ọkàn wọn si ati wá Oluwa Ọlọrun Israeli lati inu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli wá, si wá si Jerusalemu, lati ṣe irubọ si Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.

17. Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.

18. Rehoboamu si mu Mahalati, ọmọbinrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, li aya, ati Abihaili, ọmọbinrin Eliabi, ọmọ Jesse:

19. Ẹniti o bi ọmọkunrin wọnyi fun u; Jeuṣi, ati Ṣamariah, ati Sahamu.

20. Ati lẹhin rẹ̀, o mu Maaka, ọmọbinrin Absalomu ti o bi Abijah fun u, ati Attai, ati Sisa, ati Ṣelomiti.

21. Rehoboamu si fẹran Maaka ọmọbinrin Absalomu, jù gbogbo awọn aya rẹ̀ ati àle rẹ̀ lọ: (nitoriti o ni aya mejidilogun, ati ọgọta àle: o si bi ọmọkunrin mejidilọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin).

22. Rehoboamu si ṣe Abijah, ọmọ Maaka, li olori lati ṣe olori ninu awọn arakunrin rẹ̀: nitori ti o rò lati fi i jọba.

23. On si huwà ọlọgbọ́n, o si tú ninu gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ka si gbogbo ilẹ Juda ati Benjamini, si olukuluku ilu olodi: o si fun wọn li onjẹ li ọ̀pọlọpọ. O si fẹran ọ̀pọlọpọ obinrin.

2. Kro 11