Bẹ̃ni nwọn si mu ijọba Juda lagbara, nwọn mu ki Rehoboamu, ọmọ Solomoni ki o lagbara li ọdun mẹta: nitori li ọdun mẹta ni nwọn rìn li ọ̀na Dafidi ati Solomoni.