2. Kor 3:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù?

9. Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo.

10. Nitori eyi ti a tilẹ ṣe logo, kò li ogo mọ́ nitori eyi, nipasẹ ogo ti o tayọ.

11. Nitoripe bi eyi ti nkọja lọ ba li ogo, melomelo li eyi ti o duro li ogo.

12. Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ.

13. Kì si iṣe bi Mose, ẹniti o fi iboju bo oju rẹ̀, ki awọn ọmọ Israeli má ba le tẹjumọ wo opin eyi ti nkọja lọ.

14. Ṣugbọn oju-inu wọn fọ́: nitoripe titi fi di oni oloni ní kika majẹmu lailai, iboju na wà laiká soke; iboju ti a ti mu kuro ninu Kristi.

15. Ṣugbọn titi di oni oloni, nigbakugba ti a ba nkà Mose, iboju na mbẹ li ọkàn wọn.

16. Ṣugbọn nigbati on o ba yipada si Oluwa, a o mu iboju na kuro.

2. Kor 3