7. Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi.
8. Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.
9. Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ.