27. Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ.
28. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.
29. Li ọdun ikọkanla Joramu ọmọ Ahabu ni Ahasiah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda.
30. Nigbati Jehu si de Jesreeli, Jesebeli gbọ́; on si le tìrõ, o si ta ori rẹ̀, o si yọju wode ni fèrese.
31. Bi Jehu si ti ngbà ẹnu-ọ̀na wọle, o wipe, Simri ti o pa oluwa rẹ̀ ri alafia bi?
32. On si gbé oju rẹ̀ si òke fèrese, o si wipe, Tani nṣe ti emi? tani? Awọn iwẹ̀fa meji bi mẹta si yọju si i lode.
33. On si wipe, Ẹ tari rẹ̀ silẹ. Nwọn si tari rẹ̀ silẹ: diẹ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ si ta si ara ogiri, ati si ara awọn ẹṣin: on si tẹ̀ ẹ mọlẹ.
34. Nigbati o si wọle, o jẹ, o si mu, o si wipe, Ẹ lọ iwò obinrin egun yi wàyi, ki ẹ si sìn i: nitori ọmọbinrin ọba li on iṣe.
35. Nwọn si lọ isin i; ṣugbọn nwọn kó ri ninu rẹ̀ jù agbari, ati ẹsẹ̀ ati atẹ́lẹwọ rẹ̀ lọ.