Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ.