14. Ati awọn eso ti ọkàn rẹ nṣe ifẹkufẹ si, sì lọ kuro lọdọ rẹ, ati ohun gbogbo ti o dùn ti o si dara ṣegbe mọ ọ loju, a kì yio si tún ri wọn mọ́ lai.
15. Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ,
16. Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli!
17. Nitoripe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹ̃ di asan. Ati olukuluku olori ọkọ̀, ati olukuluku ẹniti nrin oju omi lọ si ibikibi, ati awọn ti nṣiṣẹ, ninu ọkọ̀, ati awọn ti nṣowo oju okun duro li òkere rére,
18. Nwọn si kigbe nigbati nwọn ri ẹ̃fin jijona rẹ̀, wipe, Ilu wo li o dabi ilu nla yi?
19. Nwọn si kù ekuru si ori wọn, nwọn kigbe, nwọn sọkun, nwọn si nṣọfọ, wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, ninu eyi ti a sọ gbogbo awọn ti o ni ọkọ̀ li okun di ọlọrọ̀ nipa ohun iyebiye rẹ̀! nitoripe ni wakati kan a sọ ọ di ahoro.
20. Yọ̀ lori rẹ̀, iwọ ọrun, ati ẹnyin aposteli mimọ́ ati woli; nitori Ọlọrun ti gbẹsan nyin lara rẹ̀.
21. Angẹli alagbara kan si gbé okuta kan soke, o dabi ọlọ nla, o si jù u sinu okun, wipe, Bayi li a o fi agbara nla bì Babiloni ilu nla nì wó, a kì yio si ri i mọ́ lai.
22. Ati ohùn awọn aludùru, ati ti awọn olorin, ati ti awọn afunfère, ati ti awọn afunpè ni a kì yio si gbọ́ ninu rẹ mọ́ rara; ati olukuluku oniṣọnà ohunkohun ni a kì yio si ri ninu rẹ mọ́ lai; ati iró ọlọ li a kì yio si gbọ́ mọ́ ninu rẹ lai;