4. Wọnyi ni igi oróro meji nì, ati ọpá fitila meji nì, ti nduro niwaju Oluwa aiye.
5. Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a.
6. Awọn wọnyi li o ni agbara lati sé ọrun, ti ojo kò fi rọ̀ li ọjọ asọtẹlẹ wọn: nwọn si ni agbara lori omi lati sọ wọn di ẹ̀jẹ, ati lati fi oniruru ajakalẹ arun kọlu aiye, nigbakugba ti nwọn ba fẹ.
7. Nigbati nwọn ba si ti pari ẹrí wọn, ẹranko ti o nti inu ọ̀gbun goke wá ni yio ba wọn jagun, yio si ṣẹgun wọn, yio si pa wọn.
8. Okú wọn yio si wà ni igboro ilu nla nì, ti a npè ni Sodomu ati Egipti nipa ti ẹmí, nibiti a gbé kàn Oluwa wọn mọ agbelebu.
9. Ati ninu awọn enia, ati ẹya, ati ède, ati orilẹ, nwọn wo okú wọn fun ijọ mẹta on àbọ, nwọn kò si jẹ ki a gbé okú wọn sinu isà okú.
10. Ati awọn ti o ngbé ori ilẹ aiye yio si yọ̀ le wọn lori, nwọn si ṣe ariya, nwọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitoriti awọn woli mejeji yi dá awọn ti o mbẹ lori ilẹ aiye loró.
11. Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn.
12. Nwọn si gbọ́ ohùn nla kan lati ọrun wá nwi fun wọn pe, Ẹ gòke wá ìhin. Nwọn si gòke lọ si ọrun ninu awọsanma; awọn ọtá wọn si ri wọn.
13. Ni wakati na ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀, idamẹwa ilu na si wó, ati ninu ìṣẹlẹ na ẹdẹgbarin enia li a pa: ẹ̀ru si ba awọn iyokù, nwọn si fi ogo fun Ọlọrun ọrun.
14. Egbé keji kọja; si kiyesi i, egbé kẹta si mbọ̀wá kánkán.