Iṣe Apo 9:16-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nitori emi o fi gbogbo ìya ti kò le ṣaijẹ nitori orukọ mi han a.

17. Anania si lọ, o si wọ̀ ile na; nigbati o si fi ọwọ́ rẹ̀ le e, o ni, Saulu Arakunrin, Oluwa li o rán mi, Jesu ti o fi ara hàn ọ li ọ̀na ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmí Mimọ́.

18. Lojukanna nkan si bọ kuro li oju rẹ̀ bi ipẹpẹ́: o si riran; o si dide, a si baptisi rẹ̀.

19. Nigbati o si jẹun, ara rẹ̀ mokun: Saulu si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Damasku ni ijọ melokan.

20. Lojukanna o si nwasu Kristi ninu awọn sinagogu pe, Ọmọ Ọlọrun li on iṣe.

21. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o ngbọ́, nwọn si wipe, Ẹniti o ti fõro awọn ti npè orukọ yi ni Jerusalemu kọ li eyi, ti o si ti itori na wá si ihinyi, lati mu wọn ni didè lọ sọdọ awọn olori alufa?

22. Ṣugbọn Saulu npọ̀ si i li agbara o si ndãmu awọn Ju ti o ngbe Damasku, o nfi hàn pe, eyi ni Kristi na.

23. Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a:

24. Ṣugbọn ìditẹ̀ wọn di mimọ̀ fun Saulu. Nwọn si nṣọ ẹnu-bode pẹlu li ọsán ati li oru lati pa a.

25. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mu u li oru, nwọn si sọ̀ ọ kalẹ lara odi ninu agbọ̀n.

26. Nigbati Saulu si de Jerusalemu, o pete ati da ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn ọmọ-ẹhin: gbogbo nwọn si bẹ̀ru rẹ̀, nitori nwọn kò gbagbọ́ pe ọmọ-ẹhin kan ni.

27. Ṣugbọn Barnaba mu u, o si sìn i lọ sọdọ awọn aposteli, o si sọ fun awọn bi o ti ri Oluwa li ọ̀na, ati pe o ti ba a sọ̀rọ, ati bi o ti fi igboiya wasu ni Damasku li orukọ Jesu.

Iṣe Apo 9