Iṣe Apo 5:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN ọkunrin kan ti a npè ni Anania, pẹlu Safira aya rẹ̀, tà ilẹ iní kan.

2. O si yàn apakan pamọ́ ninu owo na, aya rẹ̀ ba a mọ̀ ọ pọ̀, o si mu apakan rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli.

3. Ṣugbọn Peteru wipe, Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmí Mimọ́, ti iwọ si fi yàn apakan pamọ́ ninu owo ilẹ na?

4. Nigbati o wà nibẹ, tirẹ ki iṣe? nigbati a si ta a tan, kò ha wà ni ikawọ ara rẹ? Ẽha ti ṣe ti iwọ fi rò kini yi li ọkàn rẹ? enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun.

5. Nigbati Anania si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, o ṣubu lulẹ, o si kú: ẹ̀ru nla si ba gbogbo awọn ti o gbọ́.

6. Awọn ọdọmọkunrin si dide, nwọn dì i, nwọn si gbé e jade, nwọn si sin i.

7. O si to bi ìwọn wakati mẹta, aya rẹ̀ laimọ̀ ohun ti o ti ṣe, o wọle.

8. Peteru si da a lohùn pe, Wi fun mi, bi iye bayi li ẹnyin tà ilẹ na? O si wipe, Lõtọ iye bẹ̃ ni.

9. Peteru si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fohùn ṣọkan lati dán Ẹmí Oluwa wò? wò o, ẹsẹ awọn ti o sinkú ọkọ rẹ mbẹ li ẹnu ọ̀na, nwọn o si gbé ọ jade.

10. O si ṣubu lulẹ li ẹsẹ rẹ̀ lojukanna, o si kú: awọn ọdọmọkunrin si wọle, nwọn bá a o kú, nwọn si gbé e jade, nwọn sin i lẹba ọkọ rẹ̀.

11. Ẹru nla si ba gbogbo ijọ, ati gbogbo awọn ti o gbọ́ nkan wọnyi.

12. A si ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu pipọ lãrin awọn enia: gbogbo wọn si fi ọkàn kan wà ni iloro Solomoni.

13. Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn: ṣugbọn enia nkókiki wọn.

Iṣe Apo 5